Babel

The Tower of Babel (Genesis 11: 1-9)

Yoruba (èdè Yorùbá)

  1. Wàyí o, gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan àti irú àwọn ọ̀rọ̀ kan.
  2. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nínú ìrìn àjò wọn síhà ìlà-oòrùn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣàwárí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì kan ní ilẹ̀ Ṣínárì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé níbẹ̀.
  3. Olúkúlùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ẹnì kejì rẹ̀ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a ṣe àwọn bíríkì kí a sì fi ọ̀nà ìgbà sun nǹkan sun wọ́n.” Nítorí náà, bíríkì jẹ́ òkúta fún wọn, ṣùgbọ́n ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì jẹ́ erùpẹ̀ àpòrọ́ fún wọn.
  4. Wọ́n sọ wàyí pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa, kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”
  5. Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ láti rí ìlú ńlá náà àti ilé gogoro tí àwọn ọmọ ènìyàn kọ́.
  6. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà wí pé: “Wò ó! Ènìyàn kan ni wọ́n, èdè kan ni ó sì wà fún gbogbo wọn, èyí sì ni ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe. Họ́wù, wàyí o, kò sí ohun kan tí wọ́n lè ní lọ́kàn láti ṣe tí yóò jẹ́ àléèbá fún wọn.
  7. Wá nísinsìnyí! Jẹ́ kí a sọ̀ kalẹ̀ kí a sì da èdè wọn rú níbẹ̀, kí wọ́n má bàa gbọ́ èdè ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.”
  8. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Jèhófà tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n sì dẹ́kun títẹ ìlú ńlá náà dó.
  9. Ìdí nìyẹn tí a fi pe orúkọ rẹ̀ ní Bábélì, nítorí pé ibẹ̀ ni Jèhófà ti da èdè gbogbo ilẹ̀ ayé rú, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ti tú wọn ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.

From: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Information about Yoruba | Phrases | Numbers | Time | Tower of Babel | Books about Yoruba on: Amazon.com and Amazon.co.uk [affilate links]

Tower of Babel in Volta-Niger languages

Ewe, Ezaa, Fon, Igbo, Ikwo, Izi, Urhobo, Yoruba

Other Tower of Babel translations

By language | By language family

[top]


Green Web Hosting - Kualo

Why not share this page:

 

Learn a Language with gymglish

If you like this site and find it useful, you can support it by making a donation via PayPal or Patreon, or by contributing in other ways. Omniglot is how I make my living.

 

Note: all links on this site to Amazon.com, Amazon.co.uk and Amazon.fr are affiliate links. This means I earn a commission if you click on any of them and buy something. So by clicking on these links you can help to support this site.

Get a 30-day Free Trial of Amazon Prime (UK)

[top]

iVisa.com